End SARS, Kemisola Oguniyi: Láti 23/10/2020 ni Kemisola Ogunniyi ti dèrò ẹ̀wọ̀n nítorí ìwọ́de EndSARS tó fi wa bímọ sẹ́wọ̀n báyìí

Agbẹjọro Kemisola salaye ibi ti ọrọ de duro bayii

Omodebinrin Kemisola Oguniyi ti ọwọ awọn agbofinro tẹ ninu iwọde EndSARS ni Ondo ti bimọ si ahamọOlùwọ́de EndSARS bímọ tuntun nínú ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tó ti lo oṣù mẹ́jọ ní àhámọ́.

Kemisola ni wọn mu lọjọ kẹtalelogun, osu kẹwaa, ọdun 2020 nibi iwọde EndSARS ti awọn ọdọ ṣe tako ifiyajẹni lọna aito awọn ọlọpaa Naijiria.

Ninu ẹwọn ni Iya Kemisola ni pe oun ti gbọ pe ọmọ oun wa ni ipo iloyun.

Felicia Ogunsola pẹlu omije salaye gbogbo igbesẹ ti oun ati ọkọ rẹ ti gbe lori irinajo Kemisola yii pe ko le jade kuro latimọle.

Baba Kemisola ti ta ogún ìní rẹ̀ pe kí Kemi lè jáde kuro lẹ́wọ̀n lẹ́yìn ìwọ́de EndSARS láti 2020.

Oluyemi Fasipe to jẹ aṣoju EndSARS panel ni Ondo naa sọ ero tire pe o ṣoro lati ni pe ọmọdebinrin yii lọ ba nkan jẹ ko dẹ tun fi wa lẹwọn lati iye ọjọ yii wa.

Related Post

O mẹnuba agbara ofin ati ohun to n ṣẹlẹ bayii

Amofin Tope Temokun to n ṣoju fun Kemisola Oguniyi naa ba BBC Yoruba sọrọ.

O ni ṣe ọmọ tuntun ti Kemi bi lẹ́wọ̀n naa jẹbi iwọde EndSARS ni?

Amofin Tope royin awọn igbesẹ ti wọn ti gbe lati rii pe Kemi kuro lẹwọn ko to bimọ ati bayii to ti bimọ sẹwọn.

Amofin naa fi igbagbọ rẹ han pe, Kemi a jade lẹwọn loni ọjọ Aje kuro ni atimọle ni Ondo.

Gbogbo bi iroyin naa ba se n lọ ni BBC Yoruba yoo maa mu wa fun un yin.
.
.
source: BBC NEWS YORUBA

Recent Posts